1 Ní ìsinsinyìí, nípa tí oúnjẹ ti a fi rúbọ sí òrìṣà, a mọ̀ pé gbogbo wa ni a ní ìmọ̀, ìmọ̀ a máa fẹ́ mu ní gbéraga, ṣùgbọ́n ìfẹ́ ní i gbéni ró.
2 Bí ẹnkẹ́ni bá ró pé òun mọ ohun kan, kò tí ì mọ̀ bí ó ti yẹ kí ó mọ̀.
3 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fẹ́ràn Ọlọ́run nítòótọ́, òun ni ẹni tí a ṣí lójú sí ìmọ̀ àti òye Ọlọ́run.
4 Nítorí náà, ǹjẹ́ ó yẹ kí a jẹ àwọn oúnjẹ ti a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bí? Láì ṣe àní àní, gbogbo wá mọ̀ pé àwọn ère òrìṣà kì í ṣe Ọlọ́run rárá, ohun asán ni wọn ni ayé. A sì mọ̀ dájúdájú pé Ọlọ́run kansoso ní ń bẹ, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn bí kò ṣe ọ̀kan ṣoṣo.
5 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, à ní ọ̀pọ̀ Ọlọ́run kékèké mìíràn ní ọ̀run àti ní ayé (gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ “Ọlọ́run” ṣe wa náà ní ọ̀pọ̀ “Olúwa” wa).
6 Ṣùgbọ́n fún àwa Ọlọ́run kan ní ó wa, Baba, lọ́wọ́ ẹni tí ó dá ohun gbogbo, àti ti ẹni tí gbogbo wa í ṣe, àti Olúwa kan soso Jésù Kírísítì, nípaṣẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo wà, àti àwa nípaṣẹ̀ rẹ̀.