8 Ṣùgbọ́n oúnjẹ kò mú wa súnmọ́ Ọlọ́run, nítorí pé kì í ṣe bí àwa bá jẹun ni àwa buru julọ tàbí nígbà tí a kò jẹ ni àwa dára jùlọ.
9 Ṣùgbọ́n ẹ máa kíyèsí ara gidigidi nípa ìlò òmìnira yín kí ẹ má baà mú kí àwọn arákùnrin mìíràn tí í se onígbàgbọ́, tí ọkàn wọn ṣe aláìlera, subú sínú ẹ́sẹ̀.
10 Ẹ kíyèsára, nítorí bi ẹnìkan ba rí i ti iwọ ti o ni ìmọ̀ bá jókòó ti oúnjẹ ní ilé òrìṣà, ǹjẹ́ òun kò ha ni mú ọkàn le, bi ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ bá ṣe aláìlera, lati jẹ oúnjẹ tí a fi rúbọ sí òrìsà?
11 Nítorí náà, nípa ìmọ̀ rẹ ni arákùnrin aláìlera náà yóò ṣe ṣègbé, arákùnrin ẹni tí Kírísítì kú fún.
12 Bí ẹ bá dẹ́ṣẹ̀ sí arakùnrin rẹ̀ tí ẹ sì n pá ọkàn àìlera wọn lára, ẹ̀yìn ǹ dẹ́sẹ̀ sí Kírísítì jùlọ.
13 Nítorí nàá, bí ẹran tí a fi rúbọ sí àwọn òrìṣà bá máa mú arákùnrin mi dẹ́ṣẹ̀, èmi kì yóò jẹ́ ẹran mọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láàyè, nítorí n kò fẹ́ kí arákùnrin mi ṣubú sìnù ẹ̀ṣẹ̀.