1 Èmi kò ha ni òmìnira bí? Èmi kò ha ń ṣe àpósítélì bí? Èmi kò ha ti rí Jésù Olúwa bí? Ẹ̀yìn ha kọ́ ní èrè iṣẹ́ mi nínú Olúwa bí?
2 Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe àpósítélì. Dájúdájú àpósítélì ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ àpósítélì mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.
3 Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ Àpósítélì mi.
4 Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?