1 Kọ́ríńtì 9:13-19 BMY

13 Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń siṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, làti fi se ìtọ́ju ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa se àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.

14 Lọ́nà kan náà ni Olúwa ti fi àṣẹ lélẹ̀ pé, àwọn tí ń wàásù íyìnrere kí wọn sì máa jẹ́ ní ti ìyìn rere.

15 Ṣíbẹ̀síbẹ̀ n kò ì tí ì lo iru àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí rí. Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì kọ lẹ́tà yìí láti fi sọ fún un yín pé, mo fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í gbà irú nǹkan bẹ̀ẹ́ lọ́wọ́ yín. Kí a sọ òtítọ́, ó sàn fún mi láti kú sínú ebi ju pé kí n sọ ayọ̀ tí mo ní láti wàásù nù.

16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìn rere, kì í se ohun tí mo lè máa sogo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìn rere.

17 Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, nígbà náà Olúwa ní ẹ̀bùn pàtàkì fún mi, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe é tinútinú mi, mo ṣe àsìlò ìdanilójú tí a ní nínú mi.

18 Ní irú ipò báyìí, kí ni ẹ rò pé èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìn rere láèná ẹnikẹ́ni lówó, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.

19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sí i.