16 Nítorí pé bí mo ti ń wàásù ìyìn rere, kì í se ohun tí mo lè máa sogo lè. Èmi kò tilẹ̀ le è ṣe é ní, kí a tilẹ̀ sọ pé mo fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Ègbé ni fún mi tí mo bá kọ̀ láti wàásù ìyìn rere.
17 Tó bá jẹ́ pé mò ń wàásù tinútinú mi, nígbà náà Olúwa ní ẹ̀bùn pàtàkì fún mi, ṣùgbọ́n tí ń kò bá ṣe é tinútinú mi, mo ṣe àsìlò ìdanilójú tí a ní nínú mi.
18 Ní irú ipò báyìí, kí ni ẹ rò pé èrè mi ni láti jẹ́? Èrè mi ní àgbàyanu ayọ̀ tí mo ń rí gbà nípa ìwàásù ìyìn rere láèná ẹnikẹ́ni lówó, láìbéèrè ẹ̀tọ́ mi lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni.
19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì dara pọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ sí i.
20 Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn baà lè tẹ́tí sí ìwàásù ìyìn rere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kírísítì. Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin.
21 Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kírísítì), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin.
22 Nígbà tí mo bá wà láàrin àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi baà lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí.