2 Ní ìrònú àwọn ẹlòmíràn, èmi kì í ṣe àpósítélì. Dájúdájú àpósítélì ni mo jẹ́ fún un yín, tí n kì bá ṣe fún àwọn ẹlòmíràn. Nítorí èdìdì iṣẹ́ àpósítélì mi ni ẹ̀yin jẹ́ nínú Olúwa.
3 Èyí ni ìdáhùn mi sí àwọn tí ń béèrè ẹ̀tọ́ Àpósítélì mi.
4 Ṣé a kò ní ẹ̀tọ́ láti máa jẹ àti láti máa mu bí?
5 Ṣé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti máa mú ìyàwó tí í se onígbàgbọ́ káàkiri gẹ́gẹ́ bí àwọn Àpósítélì mìíràn? Àti bí arákùnrin Olúwa, àti Kéfà.
6 Ṣé kìkì Bánábà àti èmi ló yẹ kí a máa ṣisẹ́ bọ́ ara wa ni?
7 Ta ni ó síṣẹ́ ogun nígbà tí ó sanwo ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀?, Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́-ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́-ẹran?
8 Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì?