1 Kọ́ríńtì 9:7-13 BMY

7 Ta ni ó síṣẹ́ ogun nígbà tí ó sanwo ara rẹ̀? Ta ní gbin ọgbà àjàrà tí kì í jẹ nínú èso rẹ̀?, Tàbí ta ní ń bọ ọ̀wọ́-ẹran tí kì í sí ì jẹ nínú wàrà ọ̀wọ́-ẹran?

8 Èmi ha sọ nǹkan wọ̀nyí bí ènìyàn? Tàbí òfin kò wí bákan náà bì?

9 Nítorí nínú òfin tí Ọlọ́run fún Mósè, ni a tí kọ ọ́ pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń pakà nínú oko rẹ̀ lẹ́nu mọ́.” Ǹjẹ́ màlúù ni Ọlọ́run n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ bi?

10 Dájúdájú ó sọ eléyìí fún wa pé, nítorí wa ni a se kọ̀wé yìí kí ẹni tí ń tulẹ̀ lè máa tulẹ̀ ní ìrètí àti ẹni tí ń pakà lè ni ìretí láti ní ipin nínú ìkórè.

11 A ti fún irúgbìn èso ẹ̀mí sìnú ọkàn yín. Ẹ rò pé ó pọ̀jù fún wa tàbí ẹ kà á sí àṣejù, láti béèré fún oúnjẹ àti aṣọ fún àyọrísí iṣẹ́ wa bí?

12 Bí àwọn ẹlòmírán bá ní ẹ̀tọ́ tí ìrànlọ́wọ́ sì wá láti ọ̀dọ̀ yín, àwa ha kọ́ ni ó tọ́ sí jù?Ṣùgbọ́n àwa kò lo agbára yìí ṣùgbọ́n àwa faradà ohun gbogbo, kí àwa má baà ṣe ìdènà fún ìyìn rere Kírísítì.

13 Ǹjẹ́ ó yé e yín pé Ọlọ́run sọ fún àwọn tí ó ń siṣẹ́ nínú tẹ́ḿpìlì pé kí wọ́n mú oúnjẹ tàbí àwọn ẹ̀bùn tí wọ́n mú wá fún òun, làti fi se ìtọ́ju ara wọn? Àti àwọn tí ń dúró tí pẹpẹ wọn a máa se àjọpín pẹ̀lú pẹpẹ.