20 Nípa ọ̀nà títún àti ààyè, tí o yà sí mímọ́ fún wa, àti láti kọja aṣọ ìkelé èyí yìí ní, ara rẹ̀;
21 Àti bí a ti ni àlùfáà gíga lórí ilé Ọlọ́run;
22 Ẹ jẹ́ kí a fi òtítọ́ ọkàn súnmọ́ tòòsí ni ẹ̀kún ìgbàgbọ́, kí a sì wẹ ọkàn wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí ọkan búburú, kí a sì fi omi mímọ́ wẹ ara wa nù.
23 Ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ ìreti wa mu ṣinṣin ni àìsiyèméjì; (nítorí pé olóòtọ́ ní ẹni tí o ṣe ìlérí).
24 Ẹ jẹ́ kí a yẹ ara wa wò láti ru ara wa sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ rere:
25 Kí a ma máa kọ ìpejọpọ̀ ara wa sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bi àṣà àwọn ẹlòmíràn; ṣùgbọ́n kí a máa gba ara ẹni niyànjú pẹ̀lúpẹ̀lú bí ẹ̀yin ti rí i pé ọjọ́ náà ń súnmọ etílé.
26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́sẹ̀ lẹ̀yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.