10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o ba ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀.
11 Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12 Nítorí náà ẹ na ọwọ́ tí o rọ, àti èékún àìlera;
13 “Kí ẹ sì ṣe ipa-ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kuku wò ó sàn.
14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa:
15 Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “Gbòngbò ìkoro” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́.
16 Kí o má bá à si àgbérè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Èsau, ẹni tí o titorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.