3 Má a ro ti ẹni tí ó faradà irú sọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́sẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má baa rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4 Ẹ̀yin kò sáà tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yin sílẹ̀ nínú ìjakadi yín.
5 Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnánì ìbáwí Olúwa,kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:
6 Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i báwí,a sì máa na olukulùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gba.”
7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í báwí?
8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, njẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ.
9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríbà fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè?