15 Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe gbàgbé láti máa ṣoore àti láti máa pín funni nítorí irú ẹbọ wọ̀nyí ni inú Ọlọ́run dùn sí jọjọ
17 Ẹ máa gbọ́ ti àwọn tí ń ṣe olórí yín, kí ẹ sì máa tẹríbà fún wọ́n: Nítorí wọn ń ṣọ́ ẹ̀sọ́ nítorí ọkàn yín, bí àwọn ti yóò ṣe ìsírò, kí wọn lè fi ayọ̀ ṣe èyí, kì í ṣe pẹ̀lú ìbànújẹ, nítorí èyí yìí yóò jẹ àìlérè fún yín.
18 Ẹ máa gbàdúrà fún wa: Nítorí àwa gbàgbọ́ pé àwa ni ẹ̀rí ọkàn rere, a sì ń fẹ́ láti máa hùwà títọ́ nínú ohun gbogbo.
19 Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ̀ yín gidigidi sí i láti máa ṣe èyí, kí a ba lè tètè fi mi fún yín padà.
20 Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùsọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu ayérayé, àní Olúwa wa Jésù.
21 Kí ó mú yín pé nínú iṣẹ́ rere gbogbo láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó máa ṣiṣẹ ohun tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú rẹ̀ nínú yín nípasẹ̀ Jésù Kírísítì; ẹni tí ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín