Àwọn Hébérù 2:4-10 BMY

4 Ọlọ́run jẹ́rìí sí i nípa àwọn iṣẹ́ àmì àti ìyanu àti oríṣìíríṣìí iṣẹ́ agbára àti nípa ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ tí a pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.

5 Nítórí pé, kì í ṣe abẹ́ ìsàkóso àwọn ańgẹ́lì ni ó fi ayé tí ń bọ̀, tí àwa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ sí.

6 Ṣùgbọ́n ibìkan wà tí ẹnìkan tí jẹ́rìí pé:“Kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣe ìrántí rẹ̀,tàbí ọmọ ènìyàn, tí ìwọ fi ń bẹ̀ ẹ́ wò?

7 Ìwọ dá a ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ;ìwọ fi ògo àti ọlá de e ni adé,ìwọ sì fi í jẹ olórí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ:

8 Ìwọ fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.”Ní ti fí fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwa kò ì tí ì rí ohun kan tí ó kù tí kò sí ní abẹ́ àkóso rẹ̀. Ṣíbẹ̀ nísinsin yìí àwa kò ì tí ì rí pé ó fi ohun gbogbo sábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀

9 Ṣùgbọ́n àwa rí Jésù ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jésù, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

10 Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe Balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.