1 Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.
2 Ẹni tí ó lè bá àwọn aláìmòye àti àwọn tí ó ti yapa kẹ̀dùn, nítorí a fi àìlera yí òun náà ká pẹ̀lú.
3 Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe yẹ, bí ó ti ń rú ẹbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ní ń se fún ara rẹ̀ náà.
4 Ko sí ẹni tí o gba ọlá yìí fún ara rẹ̀, bí kò se ẹni tí a pè láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá gẹ́gẹ́ bí a ti pe Árọ́nì.
5 Bẹ́ẹ̀ ni Kírísítì pẹ̀lú kò si ṣe ara rẹ̀ lógo láti jẹ́ olórí àlùfáà; bí kò ṣe ẹni tí o wí fún ún pé,“Ìwọ ni ọmọ mi,lónìn-ín ni mo bi ọ.”
6 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibò mìíràn pé,“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipasẹ̀ Melikisédékì.”