6 Bí ó ti wí pẹ̀lú ní ibò mìíràn pé,“Ìwọ ni àlùfáà títí láéní ipasẹ̀ Melikisédékì.”
7 Ní ìgbà ọjọ́ Jésù nínú ayé, ó fi ẹkún rara àti omije gbàdúrà, tí ó sì bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ ẹni tí ó lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú, a sì gbóhùn rẹ̀ nítorí ó ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀.
8 Bí òun tilẹ̀ ń ṣe Ọmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ ó kọ́ gbọ́ràn nípa ohun tí ó jìyà rẹ̀;
9 Bí a sì ti sọ ọ di pípé, o wa di orísun ìgbàlà àìnípẹ̀kun fún gbogbo àwọn tí ó ń gbọ tirẹ̀:
10 Tí a yàn ní Olórí àlùfáà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ní ipasẹ̀ Melikisédékì.
11 Nípa èyí àwá ní ohun púpọ̀ láti sọ, tí ó sì ṣòro láti túmọ̀, nítorí pé ẹ yigbì ní gbígbọ́.
12 Nítorí pé báyìí ó ti yẹ kí ẹ jẹ́ olùkọ́ní, ẹ tún wà ní ẹni tí ẹnìkan yóò máa kọ́ ni ìbẹ̀rẹ̀ ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ sì tún di irú àwọn tí ó mu wàrà, tí wọn kò sì fẹ́ oúnjẹ líle.