Ẹkún Jeremaya 2:2-8 BM

2 OLUWA ti pa gbogbo ibùgbé Jakọbu run láìsí àánú.Ó ti fi ibinu wó ibi ààbò Juda lulẹ̀.Ó ti rẹ ìjọba ati àwọn aláṣẹ rẹ̀ sílẹ̀,ó fi àbùkù kàn wọ́n.

3 Ó ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,pa àwọn alágbára Israẹli;ó kọ̀, kò ràn wọ́n lọ́wọ́,nígbà tí àwọn ọ̀tá dojú kọ wọ́n.Ó jó àwọn ọmọ Jakọbu bí iná,ó sì pa gbogbo ohun tí wọn ní run.

4 Ó kẹ́ ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá,ó múra bí aninilára.Gbogbo ògo wa ló parun lójú wa,ó sì tú ibinu rẹ̀ jáde bí iná, ninu àgọ́ Sioni.

5 OLUWA ṣe bí ọ̀tá,ó ti pa Israẹli run.Ó ti pa gbogbo ààfin rẹ̀ run,ó sọ àwọn ibi ààbò rẹ̀ di àlàpàó sì sọ ọ̀fọ̀ ati ẹkún Juda di pupọ.

6 Ó wó àgọ́ rẹ̀ lulẹ̀,bí ìgbà tí eniyan wó ahéré oko.Ó pa gbogbo ibi tí wọ́n ti ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀ run.OLUWA ti fi òpin sí àwọn àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, ati ọjọ́ ìsinmi ní Sioni.Ó sì ti fi ibinu gbígbóná rẹ̀,kọ ọba ati alufaa sílẹ̀.

7 OLUWA kò bìkítà fún pẹpẹ rẹ̀ mọ́,ó sì ti kọ ibi mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.Ó ti fi odi ààfin rẹ̀ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́;wọ́n pariwo ńlá ninu ilé OLUWAgẹ́gẹ́ bíi ti ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀.

8 OLUWA ti pinnu láti wó odi Sioni lulẹ̀.Ó fi okùn ìwọ̀n wọ̀n ọ́n,kò sì rowọ́ láti parun.Ó jẹ́ kí ilé ìṣọ́ ati odi ìlú wó lulẹ̀ pẹlu ìbànújẹ́,wọ́n sì di àlàpà papọ̀.