1 Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli,
2 wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.”
3 Ṣugbọn Serubabeli, Jeṣua, ati àwọn baálé baálé tí wọ́n ṣẹ́kù ní Israẹli dá wọn lóhùn pé, “A kò fẹ́ kí ẹ bá wa lọ́wọ́ sí kíkọ́ ilé OLUWA Ọlọrun wa. Àwa nìkan ni a óo kọ́ ọ gẹ́gẹ́ bí Kirusi, ọba Pasia, ti pa á láṣẹ fún wa.”
4 Nígbà náà ni àwọn tí wọ́n ti ń gbé ilẹ̀ náà mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn ará ilẹ̀ Juda, wọ́n sì dẹ́rùbà wọ́n, kí wọ́n má baà lè kọ́ tẹmpili náà.
5 Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia.