1 Dariusi ọba pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí fínnífínní ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí ó wà ní ààfin, ní ilẹ̀ Babiloni.
2 Ṣugbọn ní ìlú Ekibatana, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Media, ni wọ́n ti rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí pé:
3 “Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27).
4 Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà.