1 Dariusi ọba pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí fínnífínní ninu àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tí ó wà ní ààfin, ní ilẹ̀ Babiloni.
2 Ṣugbọn ní ìlú Ekibatana, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Media, ni wọ́n ti rí ìwé àkọsílẹ̀ kan tí ó kà báyìí pé:
3 “Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27).
4 Kí ògiri jẹ́ ìlè igi kan lórí ìlè òkúta mẹta. Ninu ilé ìṣúra ààfin ọba ni kí wọ́n ti mú owó kí wọ́n fi san owó iṣẹ́ náà.
5 Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.”
6 Nígbà náà ni Dariusi ọba désì ìwé Tatenai pada, ó ní,“Sí Tatenai, gomina agbègbè òdìkejì odò, ati Ṣetari Bosenai ati àwọn gomina ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò.