Ẹsira 7:20-26 BM

20 Bí o bá fẹ́ ohunkohun sí i fún lílò ninu Tẹmpili Ọlọrun rẹ, gbà á ninu ilé ìṣúra ọba.

21 “Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un.

22 Ó láṣẹ láti gbà tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n kori ọkà, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati ọtí waini, ọgọrun-un (100) òṣùnwọ̀n bati òróró, ati ìwọ̀n iyọ̀ tí ó bá fẹ́.

23 Kí ẹ rí i pé ẹ tọ́jú gbogbo nǹkan tí Ọlọrun ọ̀run bá pa láṣẹ fún lílò ninu Tẹmpili rẹ̀, kí ibinu rẹ̀ má baà wá sórí ibùjókòó ọba ati àwọn ọmọ rẹ̀.

24 A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun.

25 “Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n.

26 Ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹríba fún òfin Ọlọrun rẹ ati àṣẹ ọba, pípa ni a óo pa á, tabi kí á wà á lọ kúrò ní ìlú, tabi kí á gba dúkìá rẹ̀, tabi kí á gbé e sọ sẹ́wọ̀n.”