1 Àkọsílẹ̀ àwọn eniyan ati àwọn baálé baálé tí wọ́n bá mi pada wá láti Babiloni ní àkókò Atasasesi, ọba, nìyí:
2 Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Dafidi,
3 Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
4 Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.