2 Ninu àwọn ọmọ Finehasi, Geriṣomu ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Itamari, Daniẹli ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Dafidi,
3 Hatuṣi, ọmọ Ṣekanaya, ni olórí.Ninu àwọn ọmọ Paroṣi, Sakaraya ni olórí;orúkọ aadọjọ (150) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
4 Ninu àwọn ọmọ Pahati Moabu, Eliehoenai, ọmọ Serahaya, ni olórí;orúkọ igba (200) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
5 Ninu àwọn ọmọ Satu, Ṣekanaya, ọmọ Jahasieli, ni olórí;orúkọ ọọdunrun (300) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
6 Ninu àwọn ọmọ Adini, Ebedi, ọmọ Jonatani, ni olórí;orúkọ aadọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
7 Ninu àwọn ọmọ Elamu, Jeṣaya, ọmọ Atalaya, ni olórí;orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
8 Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí;orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.