22 Ìtìjú ni ó jẹ́ fún mi láti bèèrè fún ọ̀wọ́ ọmọ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin tí yóo dáàbò bò wá ninu ìrìn àjò wa, nítorí mo ti sọ fún ọba pé Ọlọrun wa a máa ṣe rere fún àwọn tí wọ́n bá ń gbọ́ tirẹ̀; Ṣugbọn a máa fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn kò bá tẹ̀lé e.
23 Nítorí náà, a gba ààwẹ̀, a sì gbadura sí Ọlọ́run, ó sì gbọ́ tiwa.
24 Lẹ́yìn náà mo ya àwọn àgbààgbà alufaa mejila sọ́tọ̀: Ṣerebaya, Haṣabaya ati mẹ́wàá ninu àwọn arakunrin wọn.
25 Mo wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò tí ọba, ati àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ mú wá, ati èyí tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà níbẹ̀ náà mú wá fún ìlò ilé Ọlọrun.
26 Mo wọn ẹgbẹta lé aadọta (650) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ohun èlò fadaka tí a wọ̀n tó ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka, ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti wúrà,
27 ogún àwo wúrà tí wọ́n tó ẹgbẹrun (1000) ìwọ̀n diramu ati ohun èlò idẹ meji tí ó ń dán, tí ó sì níye lórí bíi wúrà.
28 Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín.