8 Ninu àwọn ọmọ Ṣefataya, Sebadaya, ọmọ Mikaeli, ni olórí;orúkọ ọgọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
9 Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
10 Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
11 Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
12 Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
13 Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.
14 Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí,orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.