9 Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
10 Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
11 Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
12 Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.
13 Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.
14 Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí,orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.
15 Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.