1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli.
2 Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.”
3 Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un.
4 OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli.
5 Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.”
6 Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́,