4 N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n.
5 Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.”
6 Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde.
7 Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.”
8 Kò gbà pé èmi ni mo fún òun ní oúnjẹ, tí mo fún un ní waini ati òróró, tí mo sì fún un ní ọpọlọpọ fadaka ati wúrà tí ó ń lò fún oriṣa Baali.
9 Nítorí náà n óo gba waini ati ọkà mi pada ní àkókò wọn, n óo sì gba aṣọ òtútù ati ẹ̀wù fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun mi, tí kì bá fi bo ìhòòhò rẹ̀.
10 N óo tú u sí ìhòòhò lójú àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, kò sì ní sí ẹni tí yóo lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ mi.