6 Oriṣa ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù kì í ṣe Ọlọrun, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni, a óo sì rún ti Samaria wómúwómú.
7 Wọ́n ń gbin afẹ́fẹ́, wọn yóo sì ká ìjì líle. Ọkà tí kò bá tú, kò lè lọ́mọ, bí wọ́n bá tilẹ̀ lọ́mọ, tí wọ́n sì gbó, àwọn àjèjì ni yóo jẹ ẹ́ run.
8 A ti tú Israẹli ká, wọ́n ti kọ́ àṣàkaṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà láàrin wọn, wọ́n sì dàbí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí pé wọ́n lọ sí Asiria, wọ́n dàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń dá rìn; Efuraimu ti bẹ àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ́wẹ̀ fún ààbò.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn fún àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, n óo kó wọn jọ láìpẹ́, láti jẹ wọ́n níyà, fún ìgbà díẹ̀, lọ́dọ̀ àwọn ọba alágbára tí yóo ni wọ́n lára.
11 “Nítorí Efuraimu ti tẹ́ ọpọlọpọ pẹpẹ láti dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, wọ́n ti di pẹpẹ ẹ̀ṣẹ̀ dídá fún un.
12 Bí mo tilẹ̀ kọ òfin mi sílẹ̀ ní ìgbà ẹgbẹrun, sibẹsibẹ wọn óo kà wọ́n sí nǹkan tó ṣàjèjì.