13 Ẹ kíyèsí ọgbọ́n Ọlọrun, nítorí pé, ta ló lè tọ́ ohun tí ó bá dá ní wíwọ́?
14 Máa yọ̀ nígbà tí ó bá dára fún ọ, ṣugbọn nígbà tí nǹkan kò bá dára, máa ranti pé Ọlọrun ló ṣe mejeeji. Nítorí náà, eniyan kò lè mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la.
15 Ninu gbogbo ìgbé-ayé asán mi, mo ti rí àwọn nǹkan wọnyi: Mo ti rí olódodo tí ó ṣègbé ninu òdodo rẹ̀, mo sì ti rí eniyan burúkú tí ẹ̀mí rẹ̀ gùn, pẹlu bí ó ti ń ṣe ibi.
16 Má jẹ́ kí òdodo rẹ pọ̀ jù, má sì gbọ́n ní àgbọ́njù; kí ni o fẹ́ pa ara rẹ fún?
17 Má ṣe burúkú jù, má sì jẹ́ òmùgọ̀. Ki ni o fẹ́ pa ara rẹ lọ́jọ́ àìpé fún?
18 Di ekinni mú ṣinṣin, má sì jẹ́ kí ekeji bọ́ lọ́wọ́ rẹ; nítorí ẹni tí ó bá bẹ̀rù Ọlọrun yóo ní ìlọsíwájú.
19 Ọgbọ́n yóo mú ọlọ́gbọ́n lágbára ju ọba mẹ́wàá lọ láàrin ìlú.