20 Kò sí olódodo kan láyé tí ń ṣe rere, tí kò lẹ́ṣẹ̀.
21 Má máa fetí sí gbogbo nǹkan tí àwọn eniyan bá wí, kí o má baà gbọ́ pé iranṣẹ rẹ kan ń bú ọ.
22 Ìwọ náà mọ̀ ní ọkàn rẹ pé, ní ọpọlọpọ ìgbà ni ìwọ náà ti bú eniyan rí.
23 Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo ti fi ọgbọ́n wádìí. Mo sọ ninu ara mi pé, “Mo fẹ́ gbọ́n,” ṣugbọn ọgbọ́n jìnnà sí mi.
24 Ta ló lè ṣe àwárí ohun tó jìnnà gbáà, tí ó jinlẹ̀ gan-an?
25 Mo tún pinnu láti kẹ́kọ̀ọ́, láti ṣe ìwádìí, ati láti wá ọgbọ́n, kí n mọ gbogbo nǹkan, ati ibi tí ń bẹ ninu ìwà òmùgọ̀, ati àìlóye tí ó wà ninu ìwà wèrè.
26 Mo rí i pé, nǹkankan wà tí ó burú ju ikú lọ: òun ni obinrin oníṣekúṣe. Ọkàn rẹ̀ dàbí tàkúté ati àwọ̀n, tí ọwọ́ rẹ̀ dàbí ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀. Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun kò ní bọ́ sọ́wọ́ rẹ̀, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kó sinu tàkúté rẹ̀.