Heberu 11:3-9 BM

3 Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.

4 Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.

5 Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.”

6 Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè.

7 Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo.

8 Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ.

9 Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà.