Heberu 13 BM

Ìsìn Tí Ó Wu Ọlọrun

1 Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn.

2 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n.

3 Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà.

4 Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè.

5 Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!”

6 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé,“Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi,ẹ̀rù kò ní bà mí.Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.”

7 Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn.

8 Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae.

9 Ẹ má ṣe jẹ́ kí oríṣìíríṣìí ẹ̀kọ́ àjèjì mu yín ṣìnà. Ohun tí ó dára ni pé kí ọkàn yín gba agbára nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun, kì í ṣe nípa ìlànà ohun tí a jẹ, tabi ohun tí a kò jẹ, irú ìlànà bẹ́ẹ̀ kò ṣe àwọn tí ó ń tẹ̀lé e ní anfaani.

10 A ní pẹpẹ ìrúbọ kan tí àwọn alufaa tí wọn ń sìn ninu àgọ́ ti ayé kò ní àṣẹ láti jẹ ninu ẹbọ rẹ̀.

11 Nítorí nígbà tí Olórí Alufaa bá wọ Ibi Mímọ́ lọ, wọ́n ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹranko rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn sísun ni wọ́n ń sun ẹran ẹbọ wọnyi lẹ́yìn ibùdó.

12 Bákan náà ni Jesu, ó jìyà lẹ́yìn odi ìlú kí ó lè sọ àwọn eniyan di mímọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ òun tìkararẹ̀.

13 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á tọ̀ ọ́ lọ lẹ́yìn ibùdó, kí á gba irú ẹ̀gàn tí ó gbà.

14 Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀!

15 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.

16 Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí.

17 Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani.

18 Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo.

19 Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín.

Ìdágbére

20-21 Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin.

22 Mo bẹ̀ yín, ará, kí ẹ gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa yìí nítorí ìwé kúkúrú ni mo kọ si yín.

23 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé wọ́n ti dá Timoti, arakunrin wa, sílẹ̀: ó ti jáde lẹ́wọ̀n. Bí ó bá tètè dé, èmi ati òun ni a óo jọ ri yín.

24 Ẹ kí gbogbo àwọn aṣiwaju yín ati gbogbo àwọn onigbagbọ. Àwọn ará láti Itali ki yín.

25 Kí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wà pẹlu gbogbo yín.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13