Heberu 11 BM

Igbagbọ

1 Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.

2 Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere.

3 Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.

4 Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.

5 Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.”

6 Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè.

7 Nípa igbagbọ ni Noa fi kan ọkọ̀ kan, nígbà tí Ọlọrun ti fi àṣírí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ hàn án. Ó fi ọ̀wọ̀ gba iṣẹ́ tí Ọlọrun rán sí i, ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ìdílé rẹ̀. Nípa igbagbọ ó fi ìṣìnà aráyé hàn, ó sì ti ipa rẹ̀ di ajogún òdodo.

8 Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi gbà nígbà tí Ọlọrun pè é pé kí ó jáde lọ sí ilẹ̀ tí òun óo fún un. Ó jáde lọ láìmọ̀ ibi tí ó ń lọ.

9 Nípa igbagbọ ni ó fi ń gbé ilẹ̀ ìlérí bí àlejò, ó ń gbé inú àgọ́ bíi Isaaki ati Jakọbu, àwọn tí wọn óo jọ jogún ìlérí kan náà.

10 Nítorí ó ń retí ìlú tí ó ní ìpìlẹ̀, tí ó jẹ́ pé Ọlọrun ni ó ṣe ètò rẹ̀ tí ó sì kọ́ ọ.

11 Nípa igbagbọ, Abrahamu ní agbára láti bímọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sara yàgàn, ó sì ti dàgbà kọjá ọmọ bíbí, Abrahamu gbà pé ẹni tí ó ṣèlérí tó gbẹ́kẹ̀lé.

12 Nítorí èyí, láti ọ̀dọ̀ ẹyọ ọkunrin kan, tí ó ti dàgbà títí, tí ó ti kú sára, ni ọpọlọpọ ọmọ ti jáde, wọ́n pọ̀ bíi ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi iyanrìn etí òkun.

13 Gbogbo àwọn wọnyi kú ninu igbagbọ. Wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ṣe ìlérí gbà, òkèèrè ni wọ́n ti rí i, wọ́n sì ń fi ayọ̀ retí rẹ̀. Wọ́n jẹ́wọ́ pé àlejò tí ń rékọjá lọ ni àwọn ní ayé.

14 Àwọn eniyan tí ó bá ń sọ̀rọ̀ báyìí fihàn pé wọ́n ń wá ìlú ti ara wọn.

15 Bí ó bá jẹ́ pé wọ́n tún ń ronú ti ibi tí wọ́n ti jáde wá, wọn ìbá ti wá ààyè láti pada sibẹ.

16 Ṣugbọn wọ́n ń dàníyàn fún ìlú tí ó dára ju èyí tí wọ́n ti jáde kúrò lọ, tíí ṣe ìlú ti ọ̀run. Nítorí náà Ọlọrun kò tijú pé kí á pe òun ní Ọlọrun wọn, nítorí ó ti ṣe ètò ìlú kan fún wọn.

17 Nípa igbagbọ ni Abrahamu fi Isaaki rúbọ nígbà tí Ọlọrun dán an wò. Ó fi ààyò ọmọ rẹ̀ rúbọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọrun ti ṣe ìlérí fún un nípa rẹ̀,

18 tí Ọlọrun ti sọ fún un pé, “Láti inú Isaaki ni ìdílé rẹ yóo ti gbilẹ̀.”

19 Èrò rẹ̀ ni pé Ọlọrun lè tún jí eniyan dìde ninu òkú. Nítorí èyí, àfi bí ẹni pé ó tún gba ọmọ náà pada láti inú òkú.

20 Nípa igbagbọ ni Isaaki fi súre fún Jakọbu ati Esau tí ó sì sọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wọn.

21 Nígbà tí Jakọbu ń kú lọ, nípa igbagbọ ni ó fi súre fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Josẹfu. Ó ń sin Ọlọrun bí ó ti tẹríba lórí ọ̀pá rẹ̀.

22 Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.

23 Nígbà tí wọ́n bí Mose, nípa igbagbọ ni àwọn òbí rẹ̀ fi gbé e pamọ́ fún oṣù mẹta nítorí wọ́n rí i pé ọmọ tí ó lẹ́wà ni, wọn kò sì bẹ̀rù àṣẹ ọba.

24 Nígbà tí Mose dàgbà tán, nípa igbagbọ ni ó fi kọ̀, tí kò jẹ́ kí wọ́n pe òun ní ọmọ ọmọbinrin Farao.

25 Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ.

26 Ó ka ẹ̀gàn nítorí Mesaya sí ọrọ̀ tí ó tóbi ju gbogbo ìṣúra Ijipti lọ, nítorí ó ń wo èrè níwájú.

27 Nípa igbagbọ ni ó fi kúrò ní Ijipti, kò bẹ̀rù ibinu ọba, ó ṣe bí ẹni tí ó rí Ọlọrun tí a kò lè rí, kò sì yẹ̀ kúrò ní ọ̀nà tí ó ti yàn.

28 Nípa igbagbọ ni ó fi ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ètò láti fi ẹ̀jẹ̀ ra ara ìlẹ̀kùn, kí angẹli tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ àwọn ará Ijipti má baà fọwọ́ kan ọmọ àwọn eniyan Israẹli.

29 Nípa igbagbọ ni àwọn ọmọ Israẹli fi gba ààrin òkun pupa kọjá bí ìgbà tí eniyan ń rìn lórí ilẹ̀ gbígbẹ. Nígbà tí àwọn ará Ijipti náà gbìyànjú láti kọjá, rírì ni wọ́n rì sinu omi.

30 Nípa igbagbọ ni odi ìlú Jẹriko fi wó lulẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti yí i ká fún ọjọ́ meje.

31 Nípa igbagbọ ni Rahabu aṣẹ́wó kò fi kú pẹlu àwọn alaigbagbọ, nígbà tí ó ti fi ọ̀yàyà gba àwọn amí.

32 Kí ni kí n tún wí? Àyè kò sí fún mi láti sọ nípa Gideoni, Baraki, Samsoni, Jẹfuta, Dafidi, Samuẹli ati àwọn wolii.

33 Nípa igbagbọ, wọ́n ṣẹgun ilẹ̀ àwọn ọba, wọn ṣiṣẹ́ tí òdodo fi gbilẹ̀, wọ́n rí ìlérí Ọlọrun gbà. Wọ́n pa kinniun lẹ́nu mọ́.

34 Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn.

35 Àwọn obinrin gba àwọn eniyan wọn tí wọ́n ti kú pada lẹ́yìn tí a ti jí wọn dìde kúrò ninu òkú.A dá àwọn mìíràn lóró títí wọ́n fi kú. Wọn kò pé kí á dá wọn sílẹ̀, nítorí kí wọ́n lè gba ajinde tí ó dára jùlọ.

36 A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n.

37 A sọ àwọn mìíràn lókùúta. A fi ayùn rẹ́ àwọn mìíràn sí meji. A fi idà pa àwọn mìíràn. Àwọn mìíràn ń rìn kiri, wọ́n wọ awọ aguntan ati awọ ewúrẹ́, ninu ìṣẹ́ ati ìpọ́njú ati ìnira.

38 Wọ́n dára ju kí wọ́n wà ninu ayé lọ. Wọ́n ń dá rìn kiri ninu aṣálẹ̀, níbi tí eniyan kì í gbé, lórí òkè, ninu ihò inú òkúta ati ihò inú ilẹ̀.

39 Gbogbo àwọn wọnyi ni ẹ̀rí rere nípa igbagbọ, ṣugbọn wọn kò rí ohun tí Ọlọrun ti ṣe ìlérí gbà.

40 Nítorí pé àwa ni Ọlọrun ní lọ́kàn tí ó fi ṣe ètò tí ó dára jùlọ, pé kí àwa ati àwọn lè jọ rí ẹ̀kún ibukun gbà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13