Heberu 10 BM

1 Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé.

2 Bí ó bá jẹ́ pé àwọn ẹbọ yìí ti sọ àwọn tí ń rú wọn di pípé ni, wọn kì bá tí rú wọn mọ́, nítorí ẹ̀rí-ọkàn wọn kì bá tí dá wọn lẹ́bi mọ́ bí ó bá jẹ́ pé ẹbọ tí wọ́n rú lẹ́ẹ̀kan bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́.

3 Ṣugbọn àwọn ẹbọ wọnyi ń mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí lọdọọdun,

4 nítorí ẹ̀jẹ̀ mààlúù ati ti ewúrẹ́ kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ.

5 Nítorí náà, nígbà tí Kristi wọ inú ayé wá, ó sọ fún Ọlọrun pé,“Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ ni o fẹ́,ṣugbọn o ti ṣe ètò ara kan fún mi.

6 Kì í ṣe ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ni o ní inú dídùn sí.

7 Nígbà náà ni mo sọ pé,‘Èmi nìyí.Àkọsílẹ̀ wà ninu Ìwé Mímọ́ nípa mi pé,Ọlọrun, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.’ ”

8 Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin.

9 Lẹ́yìn náà ó wá sọ pé, “Èmi nìyí, mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.” Èyí ni pé ó mú ti àkọ́kọ́ kúrò kí ó lè fi ekeji lélẹ̀.

10 Nípa ìfẹ́ Ọlọrun náà ni a fi yà wá sọ́tọ̀ nítorí ẹbọ tí Jesu fi ara rẹ̀ rú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

11 Àwọn alufaa a máa dúró lojoojumọ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, láti máa rú ẹbọ kan náà tí kò lè kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ nígbàkúùgbà.

12 Ṣugbọn òun ṣe ìrúbọ lẹ́ẹ̀kan fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tó fún gbogbo ìgbà, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.

13 Níbẹ̀ ni ó wà tí ó ń retí ìgbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo di àpótí-ìtìsẹ̀ rẹ̀.

14 Nítorí nípa ẹbọ kan ó sọ àwọn tí a yà sọ́tọ̀ di pípé títí lae.

15 Nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà fún wa. Ó kọ́kọ́ sọ báyìí pé,

16 “Èyí ni majẹmu tí n óo bá wọn dánígbà tí ó bá yá, Èmi Oluwa ni mo sọ bẹ́ẹ̀,Èmi óo fi òfin mi sí ọkàn wọn,n óo kọ wọ́n sí àyà wọn.”

17 Ó tún ní, “N kò ní ranti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú wọn mọ́.”

18 Nígbà tí a bá ti dárí àwọn nǹkan wọnyi ji eniyan, kò tún sí ìrúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

Ọ̀rọ̀ Ìyànjú ati Ìkìlọ̀

19 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a ní ìgboyà láti wọ Ibi Mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ ìkélé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu,

20 nípa ọ̀nà titun ati ọ̀nà ààyè tí ó ti yà sọ́tọ̀ fún wa tíí ṣe ẹran-ara rẹ̀.

21 A tún ní alufaa àgbà tí ó wà lórí ìdílé Ọlọrun.

22 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.

23 Kí á di ìjẹ́wọ́ ìrètí wa mú ṣinṣin láì ṣiyèméjì nítorí ẹni tí ó tó ó gbẹ́kẹ̀lé ni ẹni tí ó ṣe ìlérí.

24 Ẹ jẹ́ kí á máa rò nípa bí a óo ti ṣe fún ara wa ní ìwúrí láti ní ìfẹ́ ati láti ṣe iṣẹ́ rere.

25 Ẹ má jẹ́ kí á máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àṣà àwọn mìíràn, ṣugbọn kí á máa gba ara wa níyànjú, pataki jùlọ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti rí i pé ọjọ́ ńlá ọ̀hún súnmọ́ tòsí.

26 Nítorí bí a bá mọ̀ọ́nmọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn tí a ti ní ìmọ̀ òtítọ́, kò tún sí ẹbọ kan tí a lè rú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.

27 Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun.

28 Bí ẹni meji tabi mẹta bá jẹ́rìí pé ẹnìkan ṣá Òfin Mose tì, pípa ni wọn yóo pa olúwarẹ̀ láì ṣàánú rẹ̀.

29 Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́?

30 Nítorí a mọ ẹni tí ó sọ pé, “Tèmi ni ẹ̀san, Èmi yóo sì gbẹ̀san.” Ati pé, “Oluwa ni yóo ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan rẹ̀.”

31 Ohun tí ó bani lẹ́rù gidigidi ni pé kí ọwọ́ Ọlọrun alààyè tẹ eniyan.

32 Ẹ ranti bí a ti ja ìjà líle, tí ẹ farada ìrora, látijọ́, nígbà tí ẹ kọ́kọ́ rí ìmọ́lẹ̀ igbagbọ.

33 Nígbà mìíràn wọ́n fi yín ṣẹ̀sín, wọ́n jẹ yín níyà, àwọn eniyan ń fi yín ṣe ìran wò. Nígbà mìíràn ẹ̀wẹ̀, ẹ dúró láì yẹsẹ̀ pẹlu àwọn tí wọ́n ti jẹ irú ìyà bẹ́ẹ̀.

34 Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ.

35 Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹ̀mí ìfọkàntán tí ẹ ní bọ́, nítorí ó ní èrè pupọ.

36 Ohun tí ẹ nílò ni ìfaradà, kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, kí ẹ baà lè gba ìlérí tí ó ṣe.

37 Nítorí náà, bí Ìwé Mímọ́ ti wí,“Nítorí láìpẹ́ jọjọ,ẹni tí ń bọ̀ yóo dé,kò ní pẹ́ rárá.

38 Ṣugbọn àwọn olódodo tí wọ́n jẹ́ tèmiyóo wà láàyè nípa igbagbọ.Ṣugbọn bí èyíkéyìí ninu wọn bá fà sẹ́yìninú mi kò ní dùn sí i.”

39 Ṣugbọn àwa kò sí ninu àwọn tí wọn ń fà sẹ́yìn sí ìparun. Ṣugbọn àwa ní igbagbọ, a sì ti rí ìgbàlà.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13