Heberu 12 BM

Ìtọ́ni ti Oluwa

1 Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.

2 Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.

3 Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì.

4 Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú.

5 Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé,Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹmá sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí.

6 Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà,ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ,ni ó ń nà ní pàṣán.

7 Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà?

8 Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́.

9 Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè?

10 Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀.

11 Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà.

12 Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára;

13 ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun.

Ìkìlọ̀ Kí Eniyan má Kọ Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun

14 Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa.

15 Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.

16 Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má jẹ́ oníṣekúṣe tabi alaigbagbọ bíi Esau, tí ó tìtorí oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan péré ta anfaani tí ó ní gẹ́gẹ́ bí àrólé baba rẹ̀.

17 Ẹ mọ̀ pé nígbẹ̀yìn, nígbà tí ó fẹ́ gba ìre tí ó tọ́ sí àrólé, baba rẹ̀ ta á nù. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wá ọ̀nà àtúnṣe, kò sí ààyè mọ́ fún ìrònúpìwàdà.

18 Nítorí kì í ṣe òkè Sinai ni ẹ wá, níbi tí iná ti ń jó, tí ó ṣú dẹ̀dẹ̀ tí ó ṣókùnkùn tí afẹ́fẹ́ líle sì ń fẹ́,

19 tí fèrè ń dún kíkankíkan, tí ohùn kan wá ń sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà tí ó jẹ́ pé àwọn tí ń gbọ́ ọ bẹ̀bẹ̀, pé kí àwọn má tún gbọ́ irú rẹ̀ mọ́.

20 Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!”

21 Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”

22 Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan,

23 ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé,

24 ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ.

25 Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.

26 Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.”

27 Nígbà tí ó sọ pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i,” ó dájú pé nígbà tí ó mi àwọn nǹkan tí a dá wọnyi, ó ṣetán láti mú wọn kúrò patapata, kí ó lè ku àwọn ohun tí a kò mì.

28 Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti gba ìjọba tí kò ṣe é mì, ẹ jẹ́ kí á dúpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á sin Ọlọrun bí ó ti yẹ pẹlu ọ̀wọ̀ ati ẹ̀rù;

29 nítorí iná ajónirun ni Ọlọrun wa.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13