Heberu 9 BM

Ilé Ìsìn Ti Ayé ati Ti Ọ̀run

1 Majẹmu àkọ́kọ́ ni àwọn ètò ìsìn ati ilé ìsìn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ti ayé ni.

2 Nítorí wọ́n pa àgọ́ àkọ́kàn, ninu rẹ̀ ni ọ̀pá fìtílà ati tabili wà. Lórí tabili yìí ni burẹdi máa ń wà, níwájú Oluwa nígbà gbogbo. Èyí ni à ń pè ní Ibi Mímọ́.

3 Lẹ́yìn aṣọ ìkélé keji ni àgọ́ tí à ń pè ní Ibi Mímọ́ jùlọ wà.

4 Níbẹ̀ ni pẹpẹ wúrà wà fún sísun turari, ati àpótí majẹmu tí a fi wúrà bò yíká. Ninu àpótí yìí ni apẹ wúrà kékeré kan wà tí wọ́n fi mana sí ninu, ati ọ̀pá Aaroni tí ó rúwé nígbà kan rí, ati àwọn wàláà òkúta tí a kọ òfin mẹ́wàá sí.

5 Ní òkè àpótí yìí ni àwọn kerubu ògo Ọlọrun wà, tí òjìji wọn bo ìtẹ́ àánú. N kò lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan yìí fínnífínní ní àkókò yìí.

6 Bí a ti ṣe ṣe ètò gbogbo nǹkan wọnyi nìyí. Ninu àgọ́ àkọ́kàn ni àwọn alufaa ti máa ń ṣe wọlé-wọ̀de nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ìsìn wọn.

7 Ṣugbọn, Olórí Alufaa nìkan ní ó máa ń wọ inú àgọ́ keji. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún sì ni. Òun náà kò sì jẹ́ wọ ibẹ̀ láì mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí yóo fi rúbọ fún ara rẹ̀ ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn eniyan bá ṣèèṣì dá.

8 Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn nípa èyí pé ọ̀nà ibi mímọ́ kò ì tíì ṣí níwọ̀n ìgbà tí àgọ́ ekinni bá wà.

9 Àkàwé ni gbogbo èyí jẹ́ fún àkókò yìí. Àwọn ẹ̀bùn ati ẹbọ tí wọn ń rú nígbà náà kò lè fún àwọn tí ó ń rú wọn ní ìbàlẹ̀ àyà patapata.

10 Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.

11 Ṣugbọn Kristi ti dé, òun sì ni Olórí Alufaa àwọn ohun rere tí ó wà. Ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀ ninu àgọ́ tí ó pé tí ó sì tóbi ju ti àtijọ́ lọ, àgọ́ tí a kò fi ọwọ́ kọ́, tí kì í sì í ṣe ti ẹ̀dá ayé yìí.

12 Kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ tabi ti mààlúù bíkòṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀, ni ó fi rúbọ, nígbà tí ó wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láti ṣe ìràpadà ayérayé fún wa.

13 Nítorí bí ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ ati ti mààlúù ati eérú abo mààlúù tí a bù wọ́n àwọn tí wọ́n bá ṣe ohun èérí nípa ẹ̀sìn bá sọ wọ́n di mímọ́ lóde ara,

14 mélòó-mélòó ni ẹ̀jẹ̀ Kristi, tí ó fi ara rẹ̀ rú ẹbọ tí kò lábùkù sí Ọlọrun nípa Ẹ̀mí ayérayé, yóo wẹ ẹ̀rí-ọkàn wa mọ́ kúrò ninu iṣẹ́ tíí yọrí sí ikú, tí yóo sì fi ṣe wá yẹ fún ìsìn Ọlọrun alààyè.

15 Nítorí èyí, òun ni alárinà majẹmu. Ó kú kí ó lè ṣe ìràpadà fún ẹ̀ṣẹ̀ tí eniyan dá lábẹ́ majẹmu àkọ́kọ́, kí àwọn tí Ọlọrun pè lè gba ìlérí ogún ayérayé.

16 Nítorí bí eniyan bá ṣe ìwé bí òun ti fẹ́ kí wọ́n pín ogún òun, ìdánilójú kọ́kọ́ gbọdọ̀ wà pé ó ti kú kí ẹnikẹ́ni tó lè mú ìwé náà lò.

17 Ìwé ìpíngún kò wúlò níwọ̀n ìgbà tí ẹni tí ó ṣe é bá wà láàyè. Ó di ìgbà tí ó bá kú.

18 Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé pẹlu ẹ̀jẹ̀ ni a fi ṣe majẹmu àkọ́kọ́.

19 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan.

20 A wá sọ pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí Ọlọrun pa láṣẹ fun yín.”

21 Bákan náà ni yóo fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n ara àgọ́ náà ati gbogbo ohun èèlò ti ìsìn.

22 Gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti òfin, ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan pátá ni à ń fi ẹ̀jẹ̀ sọ di mímọ́, ati pé láìsí ìtasílẹ̀ ẹ̀jẹ̀ kò lè sí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Ẹbọ tí Jesu Rú Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù

23 Nítorí náà, nígbà tí ó jẹ́ pé a níláti fi ẹbọ sọ ẹ̀dà àwọn nǹkan ti ọ̀run di mímọ́, a rí i pé àwọn nǹkan ti ọ̀run fúnra wọn nílò ẹbọ tí ó dára ju èyí tí ẹ̀dà wọn gbà lọ.

24 Nítorí kì í ṣe àgọ́ tí a fi ọwọ́ kọ́ ni Kristi wọ̀ lọ, èyí tíí ṣe ẹ̀dà ti àgọ́ tòótọ́. Ṣugbọn ọ̀run gan-an ni ó wọ̀ lọ, nisinsinyii ó wà níwájú Ọlọrun nítorí tiwa.

25 Kì í sìí ṣe pé à-rú-tún-rú ni yóo máa fi ara rẹ̀ rúbọ, bí Olórí Alufaa ti ìdílé Lefi ti máa ń wọ Ibi Mímọ́ jùlọ lọ ní ọdọọdún pẹlu ẹ̀jẹ̀ tí kì í ṣe ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.

26 Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ọpọlọpọ ìgbà ni ìbá ti máa jìyà láti ìgbà tí a ti fi ìdí ayé sọlẹ̀. Ṣugbọn ó fi ara hàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nígbà tí àkókò òpin dé, láti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù nípa ẹbọ ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tí ó fi ara rẹ̀ rú.

27 Dandan ni pé kí gbogbo eniyan kú lẹ́ẹ̀kan, lẹ́yìn ikú ìdájọ́ ló kàn.

28 Bákan náà ni Kristi, nígbà tí a ti fi rúbọ lẹ́ẹ̀kan láti kó ẹ̀ṣẹ̀ ọpọlọpọ lọ, yóo tún pada lẹẹkeji, kì í ṣe láti tún ru ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, ṣugbọn láti gba àwọn tí ó ń fi ìtara retí rẹ̀ là.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13