1 Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.
2 Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.
3 Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì.
4 Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú.
5 Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé,Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹmá sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí.
6 Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà,ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ,ni ó ń nà ní pàṣán.