20 Nítorí ìjayà bá wọn nígbà tí a pàṣẹ fún wọn pé, “Bí ẹranko bá fi ara kan òkè náà, a níláti sọ ọ́ ní òkúta pa ni!”
21 Ohun tí wọ́n rí bani lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí Mose fi sọ pé, “Ẹ̀rù ń bà mí! Gbígbọ̀n ni gbogbo ara mi ń gbọ̀n látòkè délẹ̀.”
22 Ṣugbọn òkè Sioni ni ẹ wá, ìlú Ọlọrun alààyè, Jerusalẹmu ti ọ̀run, pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹrun angẹli. Ẹ wá sí àjọyọ̀ ogunlọ́gọ̀ eniyan,
23 ati ìjọ àwọn àkọ́bí tí a kọ orúkọ wọn sọ́run. Ẹ wá sọ́dọ̀ Ọlọrun onídàájọ́ gbogbo eniyan ati ọ̀dọ̀ ẹ̀mí àwọn ẹni rere tí a ti sọ di pípé,
24 ati ọ̀dọ̀ Jesu, alárinà majẹmu titun, ati sí ibi ẹ̀jẹ̀ tí a fi wọ́n ohun èèlò ìrúbọ tí ó ní ìlérí tí ó dára ju ti Abeli lọ.
25 Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.
26 Ní àkókò náà ohùn rẹ̀ mi ilẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, ó ti ṣèlérí pé, “Lẹ́ẹ̀kan sí i kì í ṣe ilẹ̀ nìkan ni n óo mì, ṣugbọn n óo mi ilẹ̀, n óo sì mi ọ̀run.”