5 Nítorí kì í ṣe àwọn angẹli ni ó fún ní àṣẹ láti ṣe àkóso ayé tí ń bọ̀, èyí tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀.
6 Ó wà ní àkọsílẹ̀ níbi tí ẹnìkan ti sọ pé,“Kí ni eniyan, tí o fi ń ranti rẹ̀,tabi ọmọ eniyan tí o fi ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
7 O dá a, ipò rẹ̀ rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli lọ fún àkókò díẹ̀.O sì fi ògo ati ọlá dé e ládé.
8 O fi gbogbo nǹkan sí ìkáwọ́ rẹ̀.”Nítorí pé ó fi gbogbo nǹkan wọnyi sí ìkáwọ́ rẹ̀, kò ku nǹkankan tí kò sí ní ìkáwọ́ rẹ̀. Ṣugbọn nígbà náà, a kò ì tíì rí i, pé gbogbo nǹkan ni ó ti wà ní ìkáwọ́ rẹ̀.
9 Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan.
10 Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ.
11 Nítorí ọ̀kan ni ẹni tí ó ń ya eniyan sí mímọ́ ati àwọn eniyan tí ó ń yà sí mímọ́ jẹ́, nítorí náà ni Jesu kò fi tijú láti pè wọ́n ní arakunrin rẹ̀.