4 Nítorí kò sí ilé kan tí kò jẹ́ pé eniyan ni ó kọ́ ọ. Ṣugbọn Ọlọrun ni ó ṣe ohun gbogbo.
5 Mose ṣe olóòótọ́ ninu gbogbo ìdílé Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ. A rán an láti jẹ́rìí sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun yóo fi fún un láti sọ ni.
6 Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.
7 Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,
8 ẹ má ṣe agídí, gẹ́gẹ́ bíi ti àkókò ìṣọ̀tẹ̀,ní àkókò ìdánwò ninu aṣálẹ̀,
9 nígbà tí àwọn baba-ńlá yín dán mi wò,tí wọ́n fi rí iṣẹ́ mi fún ogoji ọdún.
10 Nítorí náà, mo bínú sí ìran wọn.Mo ní, ‘Nígbà gbogbo ni wọ́n máa ń ṣìnà ní ọkàn wọn.Iṣẹ́ mi kò yé wọn.’