6 Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ará àtijọ́ tí wọ́n gbọ́ ìyìn rere kò wọ inú ìsinmi náà nítorí àìgbọràn, nítorí náà ó ku àwọn kan tí wọn yóo wọ inú rẹ̀.
7 Ọlọrun wá tún yan ọjọ́ mìíràn. Ninu ìwé Dafidi, tí ó kọ lẹ́yìn ọdún pupọ, ó sọ pé, “Lónìí”, níbi tí atọ́ka sí, tí ó kà báyìí pé,“Lónìí, bí ẹ bá gbọ́ ohùn rẹ̀,Ẹ má ṣe agídí.”
8 Bí ó bá jẹ́ pé Joṣua fún wọn ní ìsinmi ni, Ọlọrun kò ní tún sọ nípa ọjọ́ mìíràn mọ́ lẹ́yìn ọjọ́ pupọ.
9 Nítorí náà, ìsinmi ọjọ́ ìsinmi wà nílẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun.
10 Nítorí ẹni tí ó bá wọ inú ìsinmi rẹ̀ ti sinmi ninu iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sinmi ninu tirẹ̀.
11 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á sa gbogbo ipá wa láti wọ inú ìsinmi náà, kí ẹnikẹ́ni má tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú ati àìgbọràn bíi ti àwọn tí à ń sọ̀rọ̀ wọn.
12 Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan.