6 Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé,“Alufaa ni ọ́ títí laelaegẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”
7 Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà.
8 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ.
9 Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́.
10 Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.
11 A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí.
12 Nítorí ó ti yẹ kí ẹ di olùkọ́ni ní ọjọ́ tí ó ti pẹ́. Sibẹ ẹ tún wà ninu àwọn tí a óo máa kọ́ ní “A, B, D,” nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti Ọlọrun. Ẹ wà ninu àwọn tí a óo máa fi wàrà bọ́, ẹ kò ì tíì lè jẹ oúnjẹ gidi.