32 Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ!
33 Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀.
34 Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!”
35 Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run?
36 Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun.
37 Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa.
38 Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀.