Ìṣe Àwọn Aposteli 12 BM

Inúnibíni sí ìjọ

1 Ní àkókò náà Hẹrọdu ọba bẹ̀rẹ̀ sí ṣe inúnibíni sí àwọn kan ninu ìjọ.

2 Ó bẹ́ Jakọbu arakunrin Johanu lórí.

3 Nígbà tí ó rí i pé ó dùn mọ́ àwọn Juu, ó bá tún mú Peteru náà. Àkókò náà ni Àjọ̀dún Àìwúkàrà.

4 Ó bá mú Peteru ó tì í mọ́lé. Ó fi í lé àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun mẹrin lọ́wọ́ láti máa ṣọ́ ọ; (ọmọ-ogun mẹrin ni ó wà ní ọ̀wọ́ kọ̀ọ̀kan). Hẹrọdu fẹ́ mú Peteru wá siwaju gbogbo eniyan fún ìdájọ́ lẹ́yìn Àjọ̀dún Ìrékọjá.

5 Wọ́n bá sọ Peteru sẹ́wọ̀n, ṣugbọn gbogbo ìjọ ń fi tọkàntọkàn gbadura sí Ọlọrun nítorí rẹ̀.

Peteru Bọ́ lẹ́wọ̀n

6 Ní òru, mọ́jú ọjọ́ tí Hẹrọdu ìbá mú Peteru wá fún ìdájọ́, Peteru sùn láàrin àwọn ọmọ-ogun meji, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é; àwọn ọmọ-ogun kan sì tún wà lẹ́nu ọ̀nà, tí wọn ń ṣọ́nà.

7 Angẹli Oluwa kan bá yọ dé, ìmọ́lẹ̀ sì tàn ninu ilé náà. Angẹli náà bá rọra lu Peteru lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ní, “Dìde kíá.” Àwọn ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi de Peteru bá yọ bọ́ kúrò ní ọwọ́ rẹ̀,

8 Angẹli náà sọ fún un pé, “Di ìgbànú rẹ, sì wọ sálúbàtà rẹ.” Peteru bá ṣe bí angẹli náà ti wí. Angẹli yìí tún sọ fún un pé, “Da aṣọ rẹ bora, kí o máa tẹ̀lé mi.”

9 Ni Peteru bá tẹ̀lé e jáde. Kò mọ̀ pé òtítọ́ ni ohun tí ó ti ọwọ́ angẹli náà ṣẹlẹ̀, ó ṣebí àlá ni.

10 Wọ́n kọjá ẹ̀ṣọ́ kinni ati ekeji, wọ́n wá dé ẹnu ọ̀nà ńlá onírin tí ó jáde sinu ìlú. Fúnra ìlẹ̀kùn yìí ni ó ṣí sílẹ̀ fún wọn. Wọ́n bá jáde sí ojú ọ̀nà kan. Lójú kan náà, angẹli bá rá mọ́ Peteru lójú.

11 Ojú Peteru wá wálẹ̀. Ó ní, “Mo wá mọ̀ nítòótọ́ pé Oluwa ni ó rán angẹli rẹ̀ láti gbà mí lọ́wọ́ Hẹrọdu, ati láti yọ mí kúrò ninu ohun gbogbo tí àwọn Juu ti ń retí.”

12 Nígbà tí ó rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó lọ sí ilé Maria ìyá Johanu tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Maku. Ọpọlọpọ eniyan ni ó péjọ sibẹ tí wọn ń gbadura.

13 Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i.

14 Nígbà tí ó gbọ́ ohùn Peteru, inú rẹ̀ dùn tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi dúró ṣí ìlẹ̀kùn; ṣugbọn ó sáré lọ sinu ilé, ó lọ sọ pé Peteru wà lóde lẹ́nu ọ̀nà.

15 Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bú u pé, “Orí rẹ dàrú!” Ṣugbọn ó ṣá tẹnumọ́ ọn pé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ rí. Wọ́n wá sọ pé, “A jẹ́ pé angẹli rẹ̀ ni!”

16 Ṣugbọn Peteru tún ń kanlẹ̀kùn. Nígbà tí wọ́n ṣí i, tí wọ́n rí i, ẹnu yà wọ́n.

17 Ó bá fi ọwọ́ ṣe àmì sí wọn kí wọ́n dákẹ́; ó ròyìn fún wọn bí Oluwa ti ṣe mú òun jáde kúrò lẹ́wọ̀n. Ó ní kí wọn ròyìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jakọbu ati fún àwọn arakunrin yòókù. Ó bá jáde, ó lọ sí ibòmíràn.

18 Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú ńlá bá àwọn ọmọ-ogun. Wọn kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Peteru.

19 Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n.Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.

Bí Hẹrọdu Ṣe Kú

20 Inú bí Hẹrọdu pupọ sí àwọn ará Tire ati Sidoni. Àwọn ará ìlú wọnyi bá fi ohùn ṣọ̀kan, wọ́n wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n tu Bilasitu tíí ṣe ìjòyè ọba tí ó ń mójútó ààfin lójú, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ pé kí ọba má bínú sí àwọn nítorí láti ilé ọba ni wọ́n ti ń rí oúnjẹ jẹ.

21 Nígbà tí ó di ọjọ́ tí ọba dá fún wọn, Hẹrọdu yọ dé pẹlu aṣọ ìgúnwà rẹ̀, ó jókòó lórí ìtẹ́ rẹ̀. Ó wá bá àwọn eniyan náà sọ̀rọ̀.

22 Ni àwọn eniyan náà bá ń kígbe pé, “Ohùn Ọlọrun nìyí, kì í ṣe ti eniyan!”

23 Lẹsẹkẹsẹ angẹli Oluwa bá lù ú pa, nítorí kò fi ògo fún Ọlọrun. Ni ìdin bá jẹ ẹ́ pa.

24 Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bẹ̀rẹ̀ sí fìdí múlẹ̀ sí i, ó sì túbọ̀ ń tàn káàkiri.

25 Nígbà tí Banaba ati Saulu parí iṣẹ́ tí a rán wọn, wọ́n pada láti Jerusalẹmu, wọ́n mú Johanu tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Maku lọ́wọ́.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28