Ìṣe Àwọn Aposteli 11 BM

Peteru Ròyìn fún Ìjọ ní Jerusalẹmu

1 Àwọn aposteli ati àwọn onigbagbọ yòókù tí ó wà ní Judia gbọ́ pé àwọn tí kì í ṣe Juu náà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun.

2 Nígbà tí Peteru pada dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ tí ó jẹ́ Juu dá àríyànjiyàn sílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.

3 Wọ́n ní, “O wọlé tọ àwọn eniyan tí kò kọlà lọ, o sì bá wọn jẹun!”

4 Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ro gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn lẹ́sẹẹsẹ.

5 Ó ní, “Ìlú Jọpa ni mo wà tí mò ń gbadura, ni mo bá rí ìran kan. Nǹkankan tí ó dàbí aṣọ tí ó fẹ̀, tí wọ́n so ní igun mẹrin ń sọ̀kalẹ̀ bọ̀ láti ọ̀run títí ó fi dé ọ̀dọ̀ mi.

6 Mo tẹjú mọ́ ọn láti wo ohun tí ó wà ninu rẹ̀. Mo bá rí àwọn ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati àwọn ẹranko tí ń fi àyà wọ́, ati àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.

7 Mo wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó sọ fún mi pé, ‘Peteru, dìde, pa àwọn ẹran tí o bá fẹ́, kí o sì jẹ.’

8 Ṣugbọn mo ní, ‘Èèwọ̀, Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.’

9 Lẹẹkeji ohùn náà tún wá láti ọ̀run. Ó ní, ‘Ohunkohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ pè é ní aláìmọ́ mọ́.’

10 Ẹẹmẹta ni ó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, ni nǹkankan bá tún fa gbogbo wọn pada sí ọ̀run.

11 Lákòókò náà gan-an ni àwọn ọkunrin mẹta tí a rán sí mi láti Kesaria dé ilé tí mo wà.

12 Ẹ̀mí wá sọ fún mi pé kí n bá wọn lọ láì kọminú. Mẹfa ninu àwọn arakunrin bá mi lọ. A bá wọ ilé ọkunrin náà.

13 Ó sọ fún wa bí òun ti ṣe rí angẹli tí ó dúró ninu ilé òun tí ó sọ pé, ‘Ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o pe Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá.

14 Òun ni yóo sọ ọ̀rọ̀ fún ọ nípa bí ìwọ ati ìdílé rẹ yóo ṣe ní ìgbàlà.’

15 Bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé wọn bí ó ti bà lé wa ní àkọ́kọ́.

16 Ó mú mi ranti ọ̀rọ̀ Oluwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Omi ni Johanu fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fun yín, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀nùmọ́ yín.’

17 Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?”

18 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò tún ní ìkọminú mọ́ nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n bá ń yin Ọlọrun. Wọ́n ní, “Èyí ni pé Ọlọrun ti fún àwọn orílẹ̀-èdè yòókù náà ní anfaani láti ronupiwada kí wọ́n lè ní ìyè.”

Ìjọ ní Antioku

19 Àwọn tí ó túká nígbà inúnibíni tí ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò Stefanu dé Fonike ní Kipru ati Antioku. Wọn kò bá ẹnikẹ́ni sọ̀rọ̀ ìyìn rere àfi àwọn Juu nìkan.

20 Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn.

21 Agbára Oluwa hàn ninu iṣẹ́ wọn. Ọpọlọpọ eniyan ni wọ́n gbàgbọ́, tí wọ́n sì yipada sí Oluwa.

22 Ìròyìn dé etí ìjọ tí ó wà ní Jerusalẹmu nípa wọn. Wọ́n bá rán Banaba sí Antioku.

23 Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́.

24 Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ.

25 Banaba bá wá Paulu lọ sí Tasu.

26 Nígbà tí ó rí i, ó mú un wá sí Antioku; fún ọdún kan gbáko ni àwọn mejeeji fi wà pẹlu ìjọ, tí wọn ń kọ́ ọpọlọpọ eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Ní Antioku ni a ti kọ́ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi ní “Kristẹni.”

27 Ní àkókò náà, àwọn wolii kan wá láti Jerusalẹmu sí Antioku.

28 Ọ̀kan ninu wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agabu bá dìde. Ẹ̀mí gbé e láti sọ pé ìyàn ńlá yóo mú ní gbogbo ayé. (Èyí ṣẹlẹ̀ ní ayé ọba Kilaudiu.)

29 Ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Kristi bá pinnu pé olukuluku àwọn yóo sa gbogbo agbára rẹ̀ láti fi nǹkan ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó ń gbé Judia.

30 Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kó nǹkan rán Banaba ati Saulu sí wọn.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28