Ìṣe Àwọn Aposteli 1 BM

Jesu Ṣe Ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́

1 Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan,

2 títí di ọjọ́ tí a gbé e lọ sókè ọ̀run lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ ohun tí ó fẹ́, nípa Ẹ̀mí Mímọ́, fún àwọn aposteli tí ó ti yàn.

3 Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.

4 Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín.

5 Nítorí omi ni Johanu fi ń ṣe ìwẹ̀mọ́, ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ ni a óo fi ṣe ìwẹ̀mọ́ fun yín láìpẹ́ jọjọ.”

Jesu Gòkè Lọ sí Ọ̀run

6 Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?”

7 Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo.

8 Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.”

9 Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́.

10 Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n.

11 Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.”

A Yan Ẹlòmíràn Dípò Judasi

12 Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú.

13 Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu.

14 Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.

15 Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní,

16 “Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu.

17 Nítorí ọ̀kan ninu wa ni, ó sì ní ìpín ninu iṣẹ́ yìí.”

18 (Ó ra ilẹ̀ kan pẹlu owó tí ó gbà fún ìwà burúkú rẹ̀, ni ó bá ṣubú lulẹ̀, ikùn rẹ̀ sì bẹ́, gbogbo ìfun rẹ̀ bá tú jáde.

19 Gbogbo àwọn eniyan tí ó ń gbé Jerusalẹmu ni ó mọ̀ nípa èyí. Wọ́n bá ń pe ilẹ̀ náà ní “Akelidama” ní èdè wọn. Ìtumọ̀ èyí ni “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”)

20 “Ọ̀rọ̀ náà rí bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Ìwé Orin Dafidi pé,‘Kí ibùgbé rẹ̀ di ahoro,kí ẹnikẹ́ni má gbé ibẹ̀.’Ati pé,‘Kí á fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn.’

21-22 “Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.”

23 Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi.

24 Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn,

25 kí ó lè gba iṣẹ́ yìí ati ipò aposteli tí Judasi fi sílẹ̀ láti lọ sí ààyè tirẹ̀.”

26 Wọ́n bá ṣẹ́ gègé. Gègé bá mú Matiasi. Ó bá di ọ̀kan ninu àwọn aposteli mọkanla.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28