Ìṣe Àwọn Aposteli 15 BM

Ìgbìmọ̀ Ìjọ Jerusalẹmu

1 Àwọn kan wá láti Judia tí wọn ń kọ́ àwọn onigbagbọ pé, “Bí ẹ kò bá kọlà gẹ́gẹ́ bí àṣà ati Òfin Mose, a kò lè gbà yín là!”

2 Ó di ọ̀rọ̀ líle ati àríyànjiyàn ńlá láàrin àwọn ati Paulu ati Banaba. Ni ìjọ bá pinnu pé kí Paulu ati Banaba ati àwọn mìíràn láàrin wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli ati àwọn alàgbà ní Jerusalẹmu láti yanjú ọ̀rọ̀ náà.

3 Àwọn ìjọ sìn wọ́n sọ́nà, wọ́n wá gba Fonike ati Samaria kọjá, wọ́n ń ròyìn gẹ́gẹ́ bí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ń yipada di onigbagbọ. Èyí mú kí inú gbogbo àwọn onigbagbọ tí wọ́n gbọ́ dùn pupọ.

4 Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, gbogbo ìjọ, ati àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀. Wọ́n wá ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun ti ṣe fún wọ́n.

5 Àwọn kan láti inú ẹgbẹ́ àwọn Farisi tí wọ́n jẹ́ onigbagbọ wá dìde. Wọ́n ní, “Dandan ni pé kí á kọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí ó bá fẹ́ di onigbagbọ nílà, kí á sì pàṣẹ fún wọn láti máa pa Òfin Mose mọ́.”

6 Gbogbo àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà bá péjọ láti rí sí ọ̀rọ̀ yìí.

7 Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́.

8 Ọlọrun olùmọ̀ràn ọkàn fún wọn ní ìwé ẹ̀rí nígbà tí ó fún wọn ní Ẹ̀mí Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ti fún wa.

9 Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́.

10 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ní ṣe tí ẹ fi fẹ́ dán Ọlọrun wò, tí ẹ fẹ́ gbé àjàgà tí àwọn baba wa ati àwa náà kò tó rù, rù àwọn ọmọ-ẹ̀yìn?

11 A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.”

12 Ńṣe ni gbogbo àwùjọ dákẹ́ jẹ́ẹ́. Wọ́n wá fetí sílẹ̀ sí ohun tí Banaba ati Paulu níí sọ nípa iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu.

13 Lẹ́yìn tí wọ́n ti parí ọ̀rọ̀ tí wọ́n níí sọ, Jakọbu bá fèsì pé, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ fetí sí mi.

14 Simoni ti ròyìn ọ̀nà tí Ọlọrun kọ́kọ́ fi ṣe ìkẹ́ àwọn tí kì í ṣe Juu kí ó lè mú ninu wọn fi ṣe eniyan tirẹ̀.

15 Ọ̀rọ̀ àwọn wolii bá èyí mu, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,

16 ‘Lẹ́yìn èyí, n óo tún ilé Dafidi tí ó ti wó kọ́.N óo tún ahoro rẹ̀ mọ,n óo sì gbé e ró.

17 Báyìí ni gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo máa wá Oluwa,ati gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo ti pè láti jẹ́ tèmi.

18 Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí,ó sì jẹ́ kí á mọ ọ̀rọ̀ náà láti ìgbà àtijọ́-tijọ́.’

19 “Ní tèmi, èrò mi ni pé kí á má tún yọ àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n yipada sí Ọlọrun lẹ́nu mọ́.

20 Kàkà bẹ́ẹ̀ kí á kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n takété sí ohunkohun tí ó bá ti di àìmọ́ nítorí pé a ti fi rúbọ sí oriṣa; kí wọn má ṣe àgbèrè, kí wọn má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa, kí wọn má sì jẹ ẹ̀jẹ̀.

21 Nítorí láti ìgbà àtijọ́ ni wọ́n ti ń ké òkìkí Mose láti ìlú dé ìlú tí wọn sì ń ka ìwé rẹ̀ ninu gbogbo ilé ìpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀.”

Ìpinnu ìgbìmọ̀

22 Àwọn aposteli ati àwọn àgbà ìjọ pẹlu gbogbo ìjọ wá pinnu láti yan àwọn eniyan láàrin wọn, láti rán lọ sí Antioku pẹlu Paulu ati Banaba. Wọ́n bá yan Juda tí à ń pè ní Basaba ati Sila, tí wọn jẹ́ aṣaaju láàrin àwọn onigbagbọ.

23 Wọ́n fi ìwé rán wọn, pé:“Àwa aposteli ati àwa alàgbà kí ẹ̀yin tí kì í ṣe Juu ní Antioku, Siria ati Silisia; a kí yín bí arakunrin sí arakunrin.

24 A gbọ́ pé àwọn kan láti ọ̀dọ̀ wa ń fi ọ̀rọ̀ yọ yín lẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí ọkàn yín balẹ̀. A kò rán wọn níṣẹ́.

25 A ti wá pinnu, gbogbo wa sì fohùn sí i, a wá yan àwọn eniyan láti rán si yín pẹlu Banaba ati Paulu, àwọn àyànfẹ́ wa,

26 àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.

27 Nítorí náà a rán Juda ati Sila, láti fẹnu sọ ohun kan náà tí a kọ sinu ìwé fun yín.

28 Ẹ̀mí Mímọ́ ati àwa náà pinnu pé kí á má tún di ẹrù tí ó wúwo jù le yín lórí mọ́, yàtọ̀ sí àwọn nǹkan pataki wọnyi:

29 kí ẹ má jẹ ẹran tí a fi rúbọ sí oriṣa; kí ẹ má jẹ ẹ̀jẹ̀; kí ẹ má jẹ ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí ẹ má ṣe àgbèrè. Bí ẹ bá takété sí àwọn nǹkan wọnyi, yóo dára. Ó dìgbà o!”

30 Nígbà tí àwọn tí a rán kúrò, wọ́n dé Antioku, wọ́n pe gbogbo ìjọ, wọ́n fún wọn ní ìwé náà.

31 Nígbà tí wọ́n kà á, inú wọn dùn sí ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó wà ninu rẹ̀.

32 Juda ati Sila, tí wọ́n jẹ́ wolii fúnra wọn, tún fi ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ gba ẹgbẹ́ onigbagbọ náà níyànjú, wọ́n tún mú wọn lọ́kàn le.

33 Wọ́n dúró fún ìgbà díẹ̀, ni àwọn ìjọ bá fi tayọ̀tayọ̀ rán wọn pada lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá. [

34 Ṣugbọn Sila pinnu láti dúró níbẹ̀.]

35 Ṣugbọn Paulu ati Banaba dúró ní Antioku, wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn ati eniyan pupọ mìíràn ń waasu ọ̀rọ̀ Oluwa.

Paulu ati Banaba Gba Ọ̀nà Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀

36 Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ Paulu wí fún Banaba pé, “Jẹ́ kí á pada lọ bẹ àwọn onigbagbọ wò ní gbogbo ìlú tí a ti waasu ọ̀rọ̀ Oluwa, kí a rí bí wọ́n ti ń ṣe.”

37 Banaba fẹ́ mú Johanu tí à ń pè ní Maku lọ.

38 Ṣugbọn Paulu kò rò pé ó yẹ láti mú un lọ, nítorí ó pada lẹ́yìn wọn ní Pamfilia, kò bá wọn lọ títí dé òpin iṣẹ́ náà.

39 Àríyànjiyàn náà le tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi pínyà, tí olukuluku fi bá ọ̀nà rẹ̀ lọ. Banaba mú Maku, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru.

40 Paulu mú Sila ó bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ lẹ́yìn tí àwọn onigbagbọ ti fi í lé oore-ọ̀fẹ́ Oluwa lọ́wọ́.

41 Ó gba Siria ati Silisia kọjá, ó ń mú àwọn ìjọ lọ́kàn le.

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28