Ìṣe Àwọn Aposteli 3 BM

A Wo Arọ Kan Sàn Lẹ́nu Ọ̀nà Tẹmpili

1 Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura.

2 Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ.

3 Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ.

4 Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!”

5 Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan.

6 Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”

7 Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun.

8 Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun.

9 Gbogbo àwọn eniyan rí i tí ó ń rìn, tí ó ń yin Ọlọrun.

10 Wọ́n ṣe akiyesi pé ẹni tí ó ti máa ń jókòó ṣagbe lẹ́nu Ọ̀nà Dáradára Tẹmpili ni. Ẹnu yà wọ́n, wọ́n ta gìrì sí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkunrin náà.

Ọ̀rọ̀ tí Peteru Sọ ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni

11 Bí ọkunrin náà ti rọ̀ mọ́ Peteru ati Johanu, gbogbo àwọn eniyan sáré pẹlu ìyanu lọ sọ́dọ̀ wọn ní ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí à ń pè ní ti Solomoni.

12 Nígbà tí Peteru rí wọn, ó bi àwọn eniyan pé, “Ẹ̀yin eniyan Israẹli, kí ló dé tí èyí fi yà yín lẹ́nu? Kí ló dé tí ẹ fi tẹjú mọ́ wa bí ẹni pé nípa agbára wa tabi nítorí pé a jẹ́ olùfọkànsìn ni a fi mú kí ọkunrin yìí rìn?

13 Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀.

14 Ẹ sẹ́ ẹni Ọlọrun ati olódodo, ẹ wá bèèrè pé kí wọ́n dá apànìyàn sílẹ̀ fun yín;

15 ẹ pa orísun ìyè. Òun yìí ni Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú. Àwa gan-an ni ẹlẹ́rìí pé bẹ́ẹ̀ ló rí.

16 Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín.

17 “Ṣugbọn nisinsinyii, ará, mo mọ̀ pé ẹ kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjòyè yín náà kò mọ̀ọ́nmọ̀ ṣe é.

18 Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe mú ohun tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu gbogbo àwọn wolii rẹ̀ ṣẹ, pé Mesaya òun níláti jìyà.

19 Nítorí náà, ẹ ronupiwada, kí ẹ yipada sọ́dọ̀ Ọlọrun bí ẹ bá fẹ́ kí á pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.

20 Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu,

21 ẹni tí ó níláti wà ní ọ̀run títí di àkókò tí ohun gbogbo yóo fi di titun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ láti ìgbà àtijọ́, láti ẹnu àwọn wolii rẹ̀ mímọ́, àwọn eniyan ọ̀tọ̀.

22 Mose ṣá ti sọ pé, ‘Oluwa Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan bí èmi dìde láàrin àwọn arakunrin yín. Òun ni kí ẹ gbọ́ràn sí lẹ́nu ninu ohun gbogbo tí ó bá sọ fun yín.

23 Ẹnikẹ́ni tí kò bá gbọ́ràn sí wolii náà lẹ́nu, píparun ni a óo pa á run patapata láàrin àwọn eniyan Ọlọrun.’

24 Gbogbo àwọn wolii, láti ìgbà Samuẹli ati àwọn tí ó dé lẹ́yìn rẹ̀, fi ohùn ṣọ̀kan sí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ń sọ nípa àkókò yìí.

25 Ẹ̀yin gan-an ni ọmọ àwọn wolii; nítorí tiyín ni Ọlọrun ṣe bá àwọn baba yín dá majẹmu, nígbà tí ó sọ fún Abrahamu pé, ‘Nípa ọmọ rẹ ni n óo ṣe bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’

26 Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24 25 26 27 28