33 Ọ̀gágun bá súnmọ́ Paulu, ó mú un, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n meji dè é. Ó wá wádìí ẹni tí ó jẹ́ ati ohun tí ó ṣe.
34 Àwọn kan ninu èrò ń sọ nǹkankan; àwọn mìíràn ń sọ nǹkan mìíràn. Nígbà tí ọ̀gágun náà kò lè mọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà nítorí ariwo èrò, ó pàṣẹ pé kí wọ́n mú Paulu lọ sí àgọ́ àwọn ọmọ-ogun.
35 Nígbà tí wọ́n dé àtẹ̀gùn ilé, gbígbé ni àwọn ọmọ-ogun níláti gbé Paulu wọlé nítorí ojú àwọn èrò ti ranko.
36 Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé wọn, tí wọn ń kígbe pé, “Ẹ pa á!”
37 Bí wọ́n ti fẹ́ mú Paulu wọ inú àgọ́ ọmọ-ogun, ó sọ fún ọ̀gágun pé, “Ṣé kò léèwọ̀ bí mo bá bá ọ sọ nǹkankan?”Ọ̀gágun wá bi í léèrè pé, “O gbọ́ èdè Giriki?
38 Ìyẹn ni pé kì í ṣe ìwọ ni ará Ijipti tí ó dá rúkèrúdò sílẹ̀ láìpẹ́ yìí, tí ó kó ẹgbaaji (4000) àwọn agúnbẹ lẹ́yìn lọ sí aṣálẹ̀?”
39 Paulu dáhùn ó ní, “Juu ni mí, ará Tasu ní ilẹ̀ Silisia. Ọmọ ìlú tí ó lókìkí ni mí. Gbà mí láàyè kí n bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀.”