Ìṣe Àwọn Aposteli 25:20-26 BM

20 Ọ̀rọ̀ náà rú mi lójú; mo bá bi ọkunrin náà bí ó bá fẹ́ lọ sí Jerusalẹmu, kí á ṣe ìdájọ́ ọ̀rọ̀ náà níbẹ̀.

21 Ṣugbọn Paulu ní kí á fi òun sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí Kesari yóo fi lè gbọ́ ẹjọ́ òun. Mo bá pàṣẹ kí wọ́n fi í sílẹ̀ ní ìtìmọ́lé títí tí n óo fi lè fi ranṣẹ sí Kesari.”

22 Agiripa bá wí fún Fẹstu pé, “Èmi fúnra mi fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu ọkunrin náà.”Fẹstu dáhùn ó ní, “Ẹ óo gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ lọ́la.”

23 Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, Agiripa ati Berenike bá dé pẹlu ayẹyẹ. Wọ́n wọ gbọ̀ngàn ní ààfin pẹlu àwọn ọ̀gágun ati àwọn eniyan jàǹkànjàǹkàn ní ìlú. Fẹstu bá pàṣẹ kí wọ́n mú Paulu wá.

24 Fẹstu wá sọ pé, “Agiripa aláyélúwà ati gbogbo ẹ̀yin eniyan tí ẹ bá wa péjọ níbí. Ọkunrin tí ẹ̀ ń wò yìí ni gbogbo àwọn Juu ní Jerusalẹmu ati níbí ń yan eniyan wá rí mi nípa rẹ̀, tí wọn ń kígbe pé kò yẹ kí ó tún wà láàyè mọ́.

25 Ní tèmi n kò rí ohun kan tí ó ṣe tí ó fi jẹ̀bi ikú. Ṣugbọn nígbà tí òun fúnrarẹ̀ ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ sí ọ̀dọ̀ Kesari, mo pinnu láti fi í ranṣẹ.

26 Ṣugbọn n kò ní ohun kan pàtó láti kọ sí oluwa mi nípa rẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi mú un wá siwaju yín, pàápàá siwaju Agiripa aláyélúwà, kí n lè rí ohun tí n óo kọ nípa rẹ̀ lẹ́yìn tí a bá ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò.