3 Ó dàbí ẹni pé wọ́n ti ṣá ọ̀kan ninu àwọn orí ẹranko náà lọ́gbẹ́. Ọgbẹ́ ọ̀hún tó ohun tí ó yẹ kí ó pa á ṣugbọn ó ti jinná. Gbogbo eniyan ni wọ́n ń tẹ̀lé ẹranko yìí tí wọ́n fi ń ṣe ìran wò.
4 Wọ́n ń júbà Ẹranko Ewèlè náà nítorí pé ó fi àṣẹ fún ẹranko yìí. Wọ́n sì ń júbà ẹranko náà, wọ́n ń sọ pé, “Ta ni ó dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó tó bá a jà?”
5 A fún un ní ẹnu láti fi sọ̀rọ̀ tí ó ju ẹnu rẹ̀ lọ, ọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. A fún un ní àṣẹ fún oṣù mejilelogoji.
6 Ó bá ya ẹnu, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ àfojúdi sí Ọlọrun. Ó ń sọ ọ̀rọ̀ àfojúdi sí orúkọ Ọlọrun ati sí àgọ́ rẹ̀, ati sí àwọn tí wọ́n ń gbé ọ̀run.
7 A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.
8 Gbogbo àwọn tí wọn ń gbé inú ayé tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè bá ń júbà rẹ̀. Láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé ni a kò ti kọ orúkọ wọn sinu ìwé Ọ̀dọ́ Aguntan tí a pa.
9 Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́!